Mark 13:9-11

9 a “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí i ṣẹlẹ̀, ẹ kíyèsára! Nítorí ẹ̀yin yóò wà nínú ewu. Wọn yóò fà yín lọ ilé ẹjọ́ gbogbo. Wọn yóò fi ìyà jẹ yín nínú Sinagọgu wọn. Àwọn ènìyàn yóò fẹ̀sùn kàn yín níwájú àwọn baálẹ̀ àti níwájú àwọn ọba nítorí orúkọ mi, fún ẹ̀rí fún wọn. 10Nítorí pé ẹ gbọdọ̀ kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere náà fún gbogbo orílẹ̀-èdè kí òpin tó dé. 11 bṢùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ń fà yín lọ, tí wọ́n bá sì ń fi yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣe ṣàníyàn ṣáájú ohun tí ẹ ó sọ. Ṣùgbọ́n ohun tí bá fi fún yín ní wákàtí náà, òun ni kí ẹ̀yin kí ó wí. Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń wí, bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́.

Copyright information for YorBMYO